Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:3 - Yoruba Bible

3 Gbogbo ẹni tí kò bá jẹ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọrun. Alátakò Kristi tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀ ni irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ti dé inú ayé nisinsinyii.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Gbogbo ẹmí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, kì iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ́ pe o mbọ̀, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run: èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:3
5 Iomraidhean Croise  

Nítorí ọ̀pọ̀ ni yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo máa sọ pé, ‘Èmi gan-an ni Mesaya náà,’ wọn yóo sì tan ọpọlọpọ jẹ.


Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí.


Ta ni òpùrọ́ bí ẹni tí ó bá kọ̀ láti gbà pé Jesu ni Mesaya? Olúwarẹ̀ ni Alátakò Kristi, tí ó kọ Baba ati Ọmọ.


Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan