Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:12 - Yoruba Bible

12 Ẹnikẹ́ni kò rí Ọlọrun rí, bí a bá fẹ́ràn ọmọnikeji wa, Ọlọrun ń gbé inú wa, ìfẹ́ rẹ̀ sì ti di pípé ninu wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ẹnikẹni kò ri Ọlọrun nigba kan ri. Bi awa ba fẹràn ara wa, Ọlọrun ngbé inu wa, a si mu ifẹ rẹ̀ pé ninu wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ẹnikẹ́ni kò ri Ọlọ́run nígbà kan rí. Bí àwa bá fẹ́ràn ara wa, Ọlọ́run ń gbé inú wa, a sì mú ìfẹ́ rẹ̀ pé nínú wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:12
14 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà ni Jakọbu fi sọ ibẹ̀ ní Penieli, ó ní, “Mo ti rí Ọlọrun lojukooju, sibẹ mo ṣì wà láàyè.”


OLUWA ní, “O kò lè rí ojú mi nítorí pé eniyan kò lè rí ojú mi kí ó wà láàyè.”


Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?”


Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.


Ní gbolohun kan, àwọn nǹkan mẹta ni ó wà títí lae; igbagbọ, ìrètí, ati ìfẹ́; ṣugbọn èyí tí ó tóbi jù ninu wọn ni ìfẹ́.


Kí ọlá ati ògo jẹ́ ti Ọba ayérayé, Ọba àìkú, Ọba àìrí, Ọlọrun kan ṣoṣo, lae ati laelae. Amin.


òun nìkan tí kì í kú, tí ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí eniyan kò lè súnmọ́, tí ẹnikẹ́ni kò rí rí, tí eniyan kò tilẹ̀ lè rí. Tirẹ̀ ni ọlá ati agbára tí kò lópin. Amin.


Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn.


Ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọrun ti di pípé ninu ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé a wà ninu rẹ̀ nìyí


Ẹni tí ó bá ń pa òfin Ọlọrun mọ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà tí a fi mọ̀ pé Ọlọrun ń gbé inú wa ni nípa Ẹ̀mí tí ó ti fi fún wa.


A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀.


Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, òun fẹ́ràn Ọlọrun, tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀, èké ni. Nítorí ẹni tí kò bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ tí ó ń fojú rí, kò lè fẹ́ràn Ọlọrun tí kò rí.


Ti Ọlọrun ni àwa; Ẹni tí ó bá mọ Ọlọrun ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í bá ṣe ti Ọlọrun kò ní gbọ́ tiwa. Ọ̀nà tí a fi mọ Ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí ìtànjẹ yàtọ̀ nìyí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan