Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:1 - Yoruba Bible

1 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:1
29 Iomraidhean Croise  

Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.”


Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ.


OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ.


Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin, àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?”


“Bí ẹnikẹ́ni bá wí fun yín pé. ‘Wo Kristi níhìn-ín,’ tabi ‘Wò ó lọ́hùn-ún,’ ẹ má gbàgbọ́.


“Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín kò fi lè mọ ohun tí ó tọ̀nà?


Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí á má ṣe tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo wí pé, ‘Èmi ni Mesaya’ ati pé, ‘Àkókò náà súnmọ́ tòsí.’ Ẹ má tẹ̀lé wọn.


Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀.


Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí.


ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àtiṣe iṣẹ́ ìyanu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn iwaasu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí èké, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti túmọ̀ àwọn èdè àjèjì.


Ẹni meji tabi mẹta ni kí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀, kí àwọn yòókù máa fi òye bá ohun tí wọn ń sọ lọ.


Ẹ má máa fi ojú tẹmbẹlu ẹ̀bùn wolii.


Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin.


ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín tètè mì, tabi kí èrò yín dàrú lórí ọ̀rọ̀ pé Ọjọ́ Oluwa ti dé. Kì báà jẹ́ pé ninu ọ̀rọ̀ wa tabi ninu Ẹ̀mí ni wọ́n ti rò pé a sọ ọ́, tabi bóyá ninu àlàyékálàyé kan tabi ìwé kan tí wọ́n rò pé ọ̀dọ̀ wa ni ó ti wá.


Ẹ̀mí sọ pàtó pé nígbà tí ó bá yá, àwọn ẹlòmíràn yóo yapa kúrò ninu ẹ̀sìn igbagbọ, wọn yóo tẹ̀lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀tàn ati ẹ̀kọ́ tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù wá.


Ṣugbọn yóo túbọ̀ máa burú sí i ni fún àwọn eniyan burúkú ati àwọn ẹlẹ́tàn: wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ.


Ṣugbọn bí àwọn wolii èké ti dìde láàrin àwọn eniyan Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùkọ́ni èké yóo wà láàrin yín. Wọn óo fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ wọ ààrin yín. Wọn óo sẹ́ Oluwa wọn tí ó rà wọ́n pada, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn óo mú ìparun wá sórí ara wọn kíákíá.


Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí.


Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.


Ọpọlọpọ àwọn ẹlẹ́tàn ti dé inú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá ninu ara eniyan. Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn ati alátakò Kristi.


Olùfẹ́, má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú, ṣugbọn tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti wá. Ẹni tí ó bá ń ṣe burúkú kò mọ Ọlọrun.


Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan