Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 3:3 - Yoruba Bible

3 Gbogbo ẹni tí ó bá ní ìrètí yìí ninu Jesu yóo wẹ ara rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jesu fúnrarẹ̀, ti jẹ́ mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ani bi on ti mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Olúkúlùkù ẹni tí ó ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 3:3
21 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́, ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú.


Nítorí náà, bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ti pé ninu ìṣe rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà pé.


Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.


Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́.


Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́.


Aisaya tún sọ pé, “Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ, yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.”


Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́, nígbà tí ẹ ti ní àwọn ìlérí yìí, ẹ wẹ gbogbo ìdọ̀tí kúrò ní ara ati ẹ̀mí yín. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ patapata pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun.


Ìrètí tí ó wà fun yín ni ọ̀run, tí ẹ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìn rere, ni orísun igbagbọ ati ìfẹ́ yín.


Oluwa wa fúnrarẹ̀ ati Ọlọrun Baba wa, tí ó fẹ́ wa, tí ó fún wa ní ìtùnú ayérayé ati ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́,


Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun.


Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa.


Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú.


Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run.


Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì.


Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pè yín ti jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ́ mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín.


A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa wa, tí ó fi ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tún wa bí sí ìrètí tí ó wà láàyè nípa ajinde Jesu Kristi kúrò ninu òkú.


Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé.


Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, nígbà tí ẹ̀ ń retí nǹkan wọnyi, ẹ máa ní ìtara láti wà láì lábùkù ati láì lábàwọ́n, kí ẹ wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun.


ẹni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú Ọlọrun níláti máa gbé irú ìgbé-ayé tí Jesu fúnrarẹ̀ gbé.


Nípa bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ṣe di pípé ninu wa, kí á lè ní ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́ pé bí ó ti rí ni àwa náà rí ninu ayé yìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan