Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 3:2 - Yoruba Bible

2 Olùfẹ́, nisinsinyii ọmọ Ọlọrun ni wá. Ohun tí a óo dà kò ì tíì hàn sí wa. A mọ̀ pé nígbà tí Jesu Kristi bá yọ, bí ó ti rí ni àwa náà yóo rí, nítorí a óo rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si ti ifihàn bi awa ó ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihan, a ó dabi rẹ̀; nitori awa o ri i ani bi on ti ri.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 3:2
37 Iomraidhean Croise  

lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́, ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run.


O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí; ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ, ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.


Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi, ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí.


Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ o tí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan, fún àwọn tí ó sá di ọ́.


n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi, ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ. Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.


Ṣugbọn, ta ló lè farada ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá dé? Àwọn wo ni wọn yóo lè dúró ní ọjọ́ tí ó bá yọ? Nítorí pé ó dàbí iná alágbẹ̀dẹ tí ń yọ́ irin, ati bí ọṣẹ alágbàfọ̀ tí ń fọ nǹkan mọ́.


Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yóo rí Ọlọrun.


Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ọjọ́ tí Ọmọ-Eniyan bá yọ dé.


Nítorí wọn kò lè kú mọ́, nítorí bákan náà ni wọ́n rí pẹlu àwọn angẹli. Ọmọ Ọlọrun ni wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ajinde.


Ṣugbọn iye àwọn tí ó gbà á, ni ó fi àṣẹ fún láti di ọmọ Ọlọrun, àní àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.


Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan.


“Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.


Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá.


Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá.


Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn.


Nítorí àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó yà sọ́tọ̀ kí wọ́n lè dàbí Ọmọ rẹ̀, kí Ọmọ rẹ̀ yìí lè jẹ́ àkọ́bí láàrin ọpọlọpọ mọ̀lẹ́bí.


Nítorí nisinsinyii, à ń ríran bàìbàì ninu dígí. Ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ojú yóo kojú, a óo sì ríran kedere. Nisinsinyii, kò sí ohunkohun tí mo mọ̀ ní àmọ̀tán. Ṣugbọn nígbà náà, n óo ní ìmọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti mọ̀ mí.


Bí a ti gbé àwòrán ti ẹni erùpẹ̀ wọ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé àwòrán ti ẹni ọ̀run wọ̀.


Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́, Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí, ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.”


Kò sí aṣọ tí ó bò wá lójú. Ojú gbogbo wa ń fi ògo Oluwa hàn bí ìgbà tí eniyan ń wo ojú rẹ̀ ninu dígí. À ń pa wá dà sí ògo mìíràn tí ó tayọ ti àkọ́kọ́. Èyí jẹ́ iṣẹ́ Oluwa tí í ṣe Ẹ̀mí.


Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ.


Nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ọlọrun nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.


Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́.


ẹni tí yóo tún ara ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe kí ó lè dàbí ara tirẹ̀ tí ó lógo, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ó fi lè fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ ara rẹ̀.


Nígbà tí Kristi, ẹni tíí ṣe ẹ̀mí yín bá farahàn, ẹ̀yin náà yóo farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ògo.


Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là.


Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé.


Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbé inú rẹ̀, kí á lè ní ìgboyà nígbà tí ó bá farahàn, kí ojú má baà tì wá láti wá siwaju rẹ̀ nígbà tí ó bá dé.


Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.


Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fẹ́ wa tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọrun! Bẹ́ẹ̀ gan-an ni a sì jẹ́. Nítorí náà, ayé kò mọ̀ wá, nítorí wọn kò mọ Ọlọrun.


Ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ọmọ Ọlọrun yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù nìyí: gbogbo ẹni tí kò bá ṣe iṣẹ́ òdodo tí kò sì fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní ìgboyà níwájú Ọlọrun.


Gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba yóo fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀.


Wọn óo rí i lojukooju, orúkọ rẹ̀ yóo sì wà níwájú wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan