Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 3:11 - Yoruba Bible

11 Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 3:11
16 Iomraidhean Croise  

Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí,


Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.


Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ.


Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa.


Kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, nítorí Ọlọrun ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti fẹ́ràn ọmọnikeji yín.


Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn.


Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín.


Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀.


Ju ohun gbogbo lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ sí ara yín, nítorí ìfẹ́ bo ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.


Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá.


Olùfẹ́, bí Ọlọrun bá fẹ́ràn wa tó báyìí, ó yẹ kí àwa náà fẹ́ràn ọmọnikeji wa.


Àṣẹ tí a rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi ni pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọrun, kí ó fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ pẹlu.


Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti bí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́, ó sì mọ Ọlọrun.


Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan