Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 2:7 - Yoruba Bible

7 Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ẹnyin olufẹ, ki iṣe ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, ṣugbọn ofin atijọ ti ẹnyin ti ni li àtetekọṣe. Ofin atijọ ni ọ̀rọ na ti ẹnyin ti gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 2:7
22 Iomraidhean Croise  

Ẹ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san, tabi kí ẹ di ọmọ eniyan yín sinu, ṣugbọn ẹ níláti fẹ́ràn ọmọnikeji yín gẹ́gẹ́ bí ara yín. Èmi ni OLUWA.


Bí ẹ ti ń ṣe sí ọmọ onílé ni kí ẹ máa ṣe sí àlejò tí ó wọ̀ sọ́dọ̀ yín, ẹ fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara yín, nítorí pé ẹ̀yin pàápàá ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.


“Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ pé, ‘Fẹ́ràn aládùúgbò rẹ, kí o kórìíra ọ̀tá rẹ.’


Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.


Ni wọ́n bá ní kí ó kálọ sí Òkè Areopagu. Wọ́n wá bi í pé, “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ titun tí ò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?


Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín pẹlu gbogbo ọkàn yín, ati gbogbo ẹ̀mí yín, ati gbogbo agbára yín.


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sọ̀rọ̀ báyìí, sibẹ ó dá wa lójú nípa tiyín, ẹ̀yin àyànfẹ́, pé ipò yín dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní ohun tí ó yẹ fún ìgbàlà.


Ẹ̀yin ẹ jẹ́ kí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ máa gbé inú yín. Bí ohun tí ẹ gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin yóo máa gbé inú Ọmọ ati Baba.


Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa.


Olùfẹ́, nisinsinyii ọmọ Ọlọrun ni wá. Ohun tí a óo dà kò ì tíì hàn sí wa. A mọ̀ pé nígbà tí Jesu Kristi bá yọ, bí ó ti rí ni àwa náà yóo rí, nítorí a óo rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti rí.


Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní ìgboyà níwájú Ọlọrun.


Àṣẹ rẹ̀ nìyí: pé kí á gba orúkọ Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi, gbọ́, kí á sì fẹ́ràn ẹnìkejì wa, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fi àṣẹ fún wa.


Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé.


Olùfẹ́, bí Ọlọrun bá fẹ́ràn wa tó báyìí, ó yẹ kí àwa náà fẹ́ràn ọmọnikeji wa.


Àṣẹ tí a rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi ni pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọrun, kí ó fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ pẹlu.


Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti bí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́, ó sì mọ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan