Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 2:12 - Yoruba Bible

12 Ẹ̀yin ọmọde, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ Jesu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitoriti a dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin nitori orukọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 2:12
22 Iomraidhean Croise  

Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀; kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn.


Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ.


Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa, sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá. Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ, a ti ṣẹ̀ ọ́.


Ati pé ní orúkọ rẹ̀, kí á máa waasu ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu.


Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó ní, “Arakunrin, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”


Òun ni gbogbo àwọn wolii ń jẹ́rìí sí, tí wọ́n sọ pé gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ yóo ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀.”


Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre.


Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí orúkọ mìíràn tí a fi fún eniyan lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba eniyan là.”


Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.


Nípasẹ̀ Kristi ni a ti ní ìdáǹdè nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti rí ìdáríjì gbà fún àwọn ìrékọjá wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.


Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi.


Nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ yìí ni a fi ní ìdáǹdè, àní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa.


À ń kọ àwọn nǹkan wọnyi si yín kí ayọ̀ wa lè kún.


Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa.


Ṣugbọn bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa: olóòótọ́ ati olódodo ni òun, yóo wẹ àìṣedéédé gbogbo nù kúrò lára wa.


Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo.


Kì í ṣe pé ẹ kò mọ òtítọ́ ni mo ṣe kọ ìwé si yín, ṣugbọn nítorí pé ẹ mọ̀ ọ́n ni, kò sí irọ́ kankan tí ó lè jáde láti inú òtítọ́.


Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan