Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 2:10 - Yoruba Bible

10 Ẹni tí ó bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, ohun ìkọsẹ̀ kò sí ninu olúwarẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ẹniti o ba fẹran arakunrin rẹ̀, o ngbe inu imọlẹ, kò si si ohun ikọsẹ̀ ninu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ẹni tí ó ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì ṣí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 2:10
14 Iomraidhean Croise  

Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ, kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.


Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.”


Ṣugbọn nítorí kò ní gbòǹgbò ninu ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yóo wà fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí inúnibíni tabi ìṣòro bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, lẹsẹkẹsẹ a kùnà.


Ìdájọ́ ńlá ń bẹ fún ayé, nítorí àwọn ohun ìkọsẹ̀. Dandan ni kí àwọn ohun ìkọsẹ̀ dé, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ohun ìkọsẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ó gbé!


Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ.


Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́;


Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀.


kí ẹ lè mọ àwọn ohun tí ó dára jùlọ. Kí ẹ lè jẹ́ aláìlábùkù, kí ẹ sì wà láìsí ohun ìkùnà kan ní ọjọ́ tí Kristi bá dé.


Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà.


Ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀ wà ninu òkùnkùn; kò mọ ibi tí ó ń lọ, nítorí òkùnkùn ti fọ́ ọ lójú.


Àwa mọ̀ pé a ti rékọjá láti inú ikú sí inú ìyè, nítorí a fẹ́ràn àwọn arakunrin. Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ wà ninu ikú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan