Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:9 - Yoruba Bible

9 Ṣugbọn bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa: olóòótọ́ ati olódodo ni òun, yóo wẹ àìṣedéédé gbogbo nù kúrò lára wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:9
37 Iomraidhean Croise  

Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá.


bí wọ́n bá ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, ati ìwà burúkú tí wọ́n hù,


tẹ́tí sílẹ̀, bojú wò mí, kí o sì fetí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mò ń gbà tọ̀sán-tòru nítorí àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ, tí mo sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ ọ́. Wò ó, èmi ati ìdílé baba mi ti dẹ́ṣẹ̀.


Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀? Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi.


Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ. Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,” o sì dáríjì mí.


Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.”


Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.


Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín, jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀. Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae? Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́? Ṣebí èmi OLUWA ni? Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlà kò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi.


Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi, ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa, lábẹ́ gbogbo igi tútù; o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’


N óo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi, n óo dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati oríkunkun tí wọ́n ṣe sí mi jì wọ́n.


ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀.


N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.


Wọn kò ní fi ìbọ̀rìṣà kankan, tabi ìwà ìríra kankan tabi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, sọ ara wọn di aláìmọ́ mọ́. N óo gbà wọ́n ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìfàsẹ́yìn tí wọ́n ti dá. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.


Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín; ajagun-ṣẹ́gun ni, sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.


Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani.


Gbogbo eniyan ilẹ̀ Judia ati ti ìlú Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani.


Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!”


Baba mímọ́, ayé kò mọ̀ ọ́, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́, ó ti yé àwọn wọnyi pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.


Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni wọ́n jẹ́wọ́ ohun tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n tún tú àṣírí idán tí wọn ń pa.


Ẹni tí ó tó gbẹ́kẹ̀lé ni Ọlọrun tí ó pè yín sinu ìṣọ̀kan pẹlu ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, Oluwa wa.


Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.


Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu.


Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran,


Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí: ó dájú, ó sì yẹ ní gbígbà tọkàntọkàn, pé Kristi Jesu wá sinu ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Èmi yìí sì ni olórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.


ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.


Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí.


Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé.


Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii.


Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa.


wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé, “Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare. Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ, Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan