Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:5 - Yoruba Bible

5 Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ́ lẹnu rẹ̀ ti awa si njẹ́ fun nyin, pe imọlẹ li Ọlọrun, òkunkun kò si sí lọdọ rẹ̀ rara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:5
19 Iomraidhean Croise  

òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ; òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn.


OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi; ta ni n óo bẹ̀rù? OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóo bà mí?


Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.


Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa, òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá, nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́ ní ohun tí ó dára.


Ẹ̀yin ìdílé Jakọbu ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA.


“Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru: OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ, Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ.


Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn; ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn, ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.


Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”


Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé.


Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé.


Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”


Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”


Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi,


òun nìkan tí kì í kú, tí ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí eniyan kò lè súnmọ́, tí ẹnikẹ́ni kò rí rí, tí eniyan kò tilẹ̀ lè rí. Tirẹ̀ ni ọlá ati agbára tí kò lópin. Amin.


Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.


Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa.


Ìlú náà kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn tabi ti òṣùpá, nítorí pé ògo Ọlọrun ni ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí i; Ọ̀dọ́ Aguntan ni àtùpà ibẹ̀.


Kò ní sí òru mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní nílò ìmọ́lẹ̀ àtùpà tabi ìmọ́lẹ̀ oòrùn, nítorí Oluwa Ọlọrun wọn ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún wọn. Wọn yóo sì máa jọba lae ati laelae.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan