Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:4 - Yoruba Bible

4 À ń kọ àwọn nǹkan wọnyi si yín kí ayọ̀ wa lè kún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Awa si kọwe nkan wọnyi si nyin, ki ayọ̀ nyin ki o le di kikún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:4
10 Iomraidhean Croise  

N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi. Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù, ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ; bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.


“Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Ọkọ iyawo ni ó ni iyawo, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo, tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, á máa láyọ̀ láti gbọ́ ohùn ọkọ iyawo. Nítorí náà ayọ̀ mi yìí di ayọ̀ kíkún.


Kì í ṣe pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi agbára ti igbagbọ bọ̀ yín lọ́rùn ni, nítorí ẹ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu igbagbọ. Ṣugbọn a jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu yín ni, kí ẹ lè ní ayọ̀.


kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun.


Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo.


Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan