Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:1 - Yoruba Bible

1 Ohun tí ó ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, ohun tí a ti gbọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ ìyè, tí a ti fi ojú ara wa rí, tí a wò dáradára, tí a fi ọwọ́ wa dìmú, òun ni à ń sọ fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 EYITI o ti wà li àtetekọṣe, ti awa ti gbọ́, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa si ti tẹjumọ, ti ọwọ́ wa si ti dìmu, niti Ọrọ ìye;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Èyí tí ó wà láti àtètèkọ́ṣe, tí àwa ti gbọ́, tí àwa ti fi ojú wa rí, tí àwa sì ti tẹjúmọ́, tí ọwọ́ wa sì ti dì mú; èyí tí a kéde; ní ti ọ̀rọ̀ ìyè;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:1
23 Iomraidhean Croise  

Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni? Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀? Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.


OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.”


àwọn tí nǹkan wọnyi ṣojú wọn, tí wọ́n sì sọ fún wa.


Ẹ wo ọwọ́ mi ati ẹsẹ̀ mi, kí ẹ rí i pé èmi gan-an ni. Ẹ fọwọ́ kàn mí kí ẹ rí i, nítorí iwin kò ní ẹran-ara ati egungun bí ẹ ti rí i pé mo ní.”


(Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ojú rẹ̀ ni ó jẹ́rìí, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀, ó mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́.)


Ó wá wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá, wo ọwọ́ mi, mú ọwọ́ rẹ wá kí o fi kan ẹ̀gbẹ́ mi. Má ṣe alaigbagbọ mọ́, ṣugbọn gbàgbọ́.”


Nítorí bí Baba ti ní ìyè ninu ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ti fún ọmọ ní agbára láti ní ìyè.


Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kí wọ́n tó bí Abrahamu ni èmi ti wà.”


Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun.


Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.”


báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí.


Àwa ti rí i, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ olùgbàlà aráyé.


Àwọn ẹlẹ́rìí mẹta ni ó wà:


ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.”


“Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Oluwa Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, Olodumare.


Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.


“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana: “Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan