Numeri 9:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní13 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Faic an caibideilYoruba Bible13 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ́, tí kò lọ sí ìrìn àjò, ṣugbọn tí kò ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ni a ó yọ kúrò láàrin àwọn eniyan mi, nítorí kò mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLUWA ní àkókò rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ níláti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ13 Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Faic an caibideil |