Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 8:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Aaroni sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì fún OLUWA, ó sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 8:21
10 Iomraidhean Croise  

Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.


Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́: yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.


Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́.


Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́, Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́.


“Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi,


“Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.


Mose, Aaroni àti gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.


Lẹ́yìn èyí àwọn ọmọ Lefi lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti lọ máa ṣiṣẹ́ wọn lábẹ́ àbojútó Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.


Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́: Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan