Numeri 8:19 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní19 Nínú Israẹli, mo fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Israẹli àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-ààrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.” Faic an caibideilYoruba Bible19 Mo ti fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti inú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ ati láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn nígbà tí wọn bá súnmọ́ ibi mímọ́.” Faic an caibideilBibeli Mimọ19 Emi si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọrẹ lati inu awọn ọmọ Israeli wá, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Israeli ninu agọ́ ajọ, ati lati ma ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli: ki àrun má ba sí ninu awọn ọmọ Israeli, nigbati awọn ọmọ Israeli ba sunmọ ibi-mimọ́. Faic an caibideil |