Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:86 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

86 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwo wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì (120).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

86 Ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àwo kòtò mejeejila tí wọ́n kún fún turari jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá mẹ́wàá. Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n àwọn àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe jẹ́ ọgọfa (120) ṣekeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

86 Ṣibi wurà jẹ́ mejila, nwọn kún fun turari, ṣibi kọkan jẹ́ ṣekeli mẹwa, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; gbogbo wurà agọ́ na jẹ́ ọgọfa ṣekeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:86
6 Iomraidhean Croise  

Ọpọ́n kìkì wúrà, alumagaji fìtílà, àti àwokòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára; àti àgbékọ́ wúrà fún ìlẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ìlẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹmpili.


Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà ṣe àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde.


Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa.


Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.


Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, àgbò méjìlá, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá.


Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan