Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 7:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Wọ́n mú ọrẹ wọn wá síwájú Olúwa: kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà ti abo, àti akọ màlúù kan láti ọ̀dọ̀ olórí kọ̀ọ̀kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù kan láti ọ̀dọ̀ olórí méjì. Wọ́n sì kó wọn wá sí iwájú àgọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 mú ọrẹ ẹbọ wá siwaju OLUWA. Ọkọ̀ ẹrù mẹfa ati akọ mààlúù mejila. Ọkọ̀ ẹrù kọ̀ọ̀kan fún olórí meji meji, ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan fún olórí kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mú àwọn ẹbọ wọnyi wá sí ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 7:3
7 Iomraidhean Croise  

“A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí: Ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Ejibiti fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá.


Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí. Josẹfu fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Farao ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìnàjò wọn pẹ̀lú.


Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.


“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi.


Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́.


“Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.


Olúwa sọ fún Mose pé:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan