Numeri 7:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní13 Ọrẹ rẹ̀ jẹ́: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; Faic an caibideilYoruba Bible13 Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Faic an caibideilBibeli Mimọ13 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Faic an caibideil |