Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 “ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 “Bí ẹnìkan bá kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lójijì, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ orí rẹ̀ di aláìmọ́; yóo dúró fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje tí í ṣe ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, yóo fá irun orí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:9
11 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti ṣe ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí ó rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.


“Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.


Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.


“ ‘Nígbà náà ni Nasiri náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà.


Ní gbogbo àsìkò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.


Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea: nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́.


Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un.


Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan