Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Kí Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Kí OLUWA mú kí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí yín lára, kí ó sì ṣàánú fún yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:25
15 Iomraidhean Croise  

Bí ó ti wò yíká tí ó sì rí Benjamini àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan an. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún ọ, ọmọ mi”


Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.


Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un: ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.


Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.


Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.


Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa, kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,


Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára; kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.


Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára; jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa, kí a ba à lè gbà wá là.


Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.


Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún.


“Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ Olúwa, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro.


“Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.


Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.


Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Romu tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́: Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan