Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 6:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 “ ‘Èyí ni òfin Nasiri tó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ rẹ̀ sí Olúwa, yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Nasiri, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tó lágbára láti mú wá. Ó gbọdọ̀ mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Nasiri.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 “Èyí ni òfin Nasiri, ṣugbọn bí Nasiri kan bá ṣe ìlérí ju ẹbọ tí òfin là sílẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ mú ìlérí náà ṣẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Eyi li ofin ti Nasiri ti o ṣe ileri, ati ti ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA fun ìyasapakan rẹ̀ li àika eyiti ọwọ́ on le tẹ̀: gẹgẹ bi ileri ti o ṣe, bẹ̃ni ki o ṣe nipa ofin ìyasapakan rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 6:21
7 Iomraidhean Croise  

Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.


“ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe a ṣe má ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́


“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ sí Olúwa nípa àìgé irun orí (Nasiri):


Àlùfáà yóò fi gbogbo rẹ̀ níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú igẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè mu wáìnì.


Olúwa sọ fún Mose pé,


Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni.


Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan