Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:26 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

26 Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

26 Lẹ́yìn náà, alufaa yóo bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà fún ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ; lẹ́yìn náà, yóo ní kí obinrin náà mu omi yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

26 Ki alufa ki o si bù ikunwọ kan ninu ẹbọ ohunjijẹ na, ani iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ, lẹhin eyinì ki o jẹ ki obinrin na mu omi na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:26
5 Iomraidhean Croise  

kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.


Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.


Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni


Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.


Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan