Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Nígbà náà ni alufaa yóo gba ẹbọ ohun jíjẹ ti owú náà lọ́wọ́ obinrin náà yóo sì fì í níwájú OLUWA, lẹ́yìn èyí, yóo gbé e sórí pẹpẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Nigbana li alufa yio gbà ẹbọ ohunjijẹ owú na li ọwọ́ obinrin na, yio si fì ẹbọ ohunjijẹ na niwaju OLUWA, yio si ru u lori pẹpẹ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:25
6 Iomraidhean Croise  

Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.


Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.


nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.


Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnrarẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.


Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi.


Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan