Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 5:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹrà dànù.” “ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Kí omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí wọ inú rẹ, kí ó mú kí inú rẹ wú, kí ó sì mú kí abẹ́ rẹ rà.’ “Obinrin náà yóo sì dáhùn pé, ‘Amin, Amin.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Ati omi yi ti nmú egún wá ki o wọ̀ inu rẹ lọ, lati mu inu rẹ wú, ati lati mu itan rẹ rà: ki obinrin na ki o si wipe, Amin, amin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 5:22
16 Iomraidhean Croise  

Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi


Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli láé àti láéláé. Àmín àti Àmín.


Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé; kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀. Àmín àti Àmín.


Olùbùkún ní Olúwa títí láé. Àmín àti Àmín.


Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún


Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwé kíká tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.


“ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé kíká, yóò sì sìn ín sínú omi kíkorò náà.


Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.


Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa.


Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”


Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan