Numeri 5:15 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní15 nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí. Faic an caibideilYoruba Bible15 kí olúwarẹ̀ mú iyawo rẹ̀ wá sọ́dọ̀ alufaa, kí ó sì mú ọrẹ rẹ̀ tíí ṣe ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun ọkà baali wá fún alufaa. Kò gbọdọ̀ da òróró sí orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ fi turari sinu rẹ̀, nítorí pé ẹbọ owú ni, tí a rú láti múni ranti àìdára tí eniyan ṣe. Faic an caibideilBibeli Mimọ15 Nigbana ni ki ọkunrin na ki o mú aya rẹ́ tọ̀ alufa wá, ki o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun u, idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun barle; ki o máṣe dà oróro sori rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sinu rẹ̀; nitoripe ẹbọ ohunjijẹ owú ni, ẹbọ ohunjijẹ iranti ni, ti nmú irekọja wá si iranti. Faic an caibideil |