Numeri 4:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Faic an caibideilYoruba Bible3 Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ. Faic an caibideil |
Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn arákùnrin yòókù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jerusalẹmu) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Lefi tí ó tó ọmọ-ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé Olúwa.