Numeri 4:26 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní26 Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí àgbàlá, okùn àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìsìn, àti ohun gbogbo tí à ń lò fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa sìn. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Faic an caibideilYoruba Bible26 Aṣọ ìkélé ti àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, aṣọ ìkélé fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá, ati okùn wọn, ati gbogbo àwọn ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Àwọn ni wọn óo máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó bá jẹ mọ́ àwọn nǹkan wọnyi. Faic an caibideilBibeli Mimọ26 Ati aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́ ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn wọn, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin wọn, ati ohun gbogbo ti a ṣe fun wọn; bẹ̃ni nwọn o ma sìn. Faic an caibideil |