Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 34:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 kọjá lọ sí gúúsù Akrabbimu, tẹ̀síwájú lọ si Sini: kó bọ́ si gúúsù Kadeṣi-Barnea, kí o sì dé Hasari-Addari, kí o sì kọjá sí Asmoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ki opinlẹ nyin ki o si yí lati gusù wá si ìgoke Akrabbimu, ki o si kọja lọ si Sini: ati ijadelọ rẹ̀ ki o jẹ́ ati gusù lọ si Kadeṣi-barnea, ki o si dé Hasari-addari, ki o si kọja si Asmoni:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 34:4
9 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati.


Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.


Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín.


Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi-Barnea láti lọ wo ilẹ̀ náà.


“ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,


Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.


Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Akrabbimu kọjá lọ sí Sela àti síwájú sí i.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan