Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 34:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Njẹ ki ìha gusù nyin ki o jẹ́ ati aginjù Sini lọ titi dé ẹba Edomu, ati opinlẹ gusù nyin ki o jẹ́ lati opin Okun Iyọ̀ si ìha ìla-õrùn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 34:3
9 Iomraidhean Croise  

Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí Àfonífojì Siddimu (Òkun iyọ̀).


“Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun pupa títí dé Òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate: Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ.


Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu.


Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá.


Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati.


Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.


omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan