Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 34:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ si Jordani, ijadelọ rẹ̀ yio jẹ Okun Iyọ̀: eyi ni yio jẹ́ ilẹ nyin gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀ yiká kiri.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 34:12
10 Iomraidhean Croise  

Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run).


Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí Àfonífojì Siddimu (Òkun iyọ̀).


“Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun pupa títí dé Òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate: Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ.


Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu.


Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn.


Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀.


“ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,


Nígbà tí Joṣua sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.


Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jordani. Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí Òkun ní ẹnu Jordani,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan