Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 33:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrín wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 33:4
8 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn, ààyò gbogbo ipá wọn.


“Ní òru ọjọ́ yìí kan náà ni Èmi yóò la gbogbo ilẹ̀ Ejibiti kọjá, èmi yóò sì pa gbogbo àkọ́bí àti ènìyàn, àti ẹranko, èmi yóò mú ìdájọ́ wà sí orí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Ejibiti. Èmi ni Olúwa.”


Mo mọ nísinsin yìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Ejibiti.”


Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti: Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti. Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.


Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn; nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run. Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn, olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.


nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan