Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ sí Àfonífojì Eṣkolu tí wọ́n rí ilẹ̀ náà, wọ́n mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Israẹli láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Wọ́n lọ títí dé àfonífojì Eṣikolu, wọ́n wo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n pada dé, wọ́n mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì, kí wọn má lè lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nitoripe nigbati nwọn gòke lọ dé afonifoji Eṣkolu, ti nwọn si ri ilẹ na, nwọn tán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju, ki nwọn ki o má le lọ sinu ilẹ ti OLUWA ti fi fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:9
5 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí wọ́n dé Àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú.


Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀.


Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan