Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Tí a bá rí ojúrere rẹ,” wọ́n wí, “jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má ṣe jẹ́ kí a rékọjá odò Jordani.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:5
11 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojúrere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, Èmi kò le è sálọ sórí òkè, kí búburú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú.


Joabu sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Joabu sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.”


Nígbà tí ó rí ayaba Esteri tí ó dúró nínú àgbàlá, inú rẹ̀ yọ́ sí i, ọba sì na ọ̀pá aládé wúrà ọwọ́ rẹ̀ sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ṣe súnmọ́ ọn ó sì fi ọwọ́ kan orí ọ̀pá náà.


Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.”


Ni ilẹ̀ tí Olúwa ti ṣẹ́gun níwájú ìjọ Israẹli tí ó sì dára fún ohun ọ̀sìn, ṣáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ohun ọ̀sìn.


Mose sọ fún àwọn ọmọ Gadi àti fún ọmọ Reubeni pé, “Ṣé kí àwọn arákùnrin yín lọ sí ogun, kí ẹ̀yin kí ó sì jókòó sí bí?


Torí i tiyín ni Olúwa fi bínú sí mi wí pé, “Ìwọ náà kì yóò wọ ibẹ̀ bákan náà,


Joṣua sì wí pé, “Háà, Olúwa Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani?


Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?”


Ṣùgbọ́n Dafidi tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojúrere ní ojú rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jonatani kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Síbẹ̀ nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láààyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrín ìyè àti ikú.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan