Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 “Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:3
22 Iomraidhean Croise  

“Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Sihoni ará a Heṣboni àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani.


Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ àwọn koríko sì ti gbẹ, gbogbo ewéko ti tán ewé tútù kankan kò sí mọ́.


Ní ti Moabu: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun. A dójútì Kiriataimu, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.


Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.


Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún ìwọ àjàrà Sibma. Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun, wọn dé Òkun Jaseri. Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ, ìkórè èso àjàrà rẹ.


“Ohùn igbe wọn gòkè láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi, láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi, nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ


“Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni, yóò sì jó iwájú orí Moabu run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.


nítorí náà Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu.


“Iná jáde láti Heṣboni, ọ̀wọ́-iná láti Sihoni. Ó jó Ari àti Moabu run, àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.


“Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú; A ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni. A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa, tí ó sì fi dé Medeba.”


Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde.


Àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilẹ̀ Jaseri àti Gileadi dára fún ohun ọ̀sìn.


Àwọn ọmọ Gadi àti àwọn ọmọ Reubeni sì wá, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà àti sí olórí gbogbo ìlú, wọ́n sì wí pé,


sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni,


Kiriataimu, Sibma, Sereti Ṣahari lórí òkè ní àfonífojì.


Heṣboni àti Jaseri, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.


Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan