Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 32:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 ‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Ejibiti ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Abrahamu, fún Isaaki àti fún Jakọbu:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 ‘Ọ̀kan ninu àwọn tí ó ti ilẹ̀ Ijipti wá, láti ẹni ogún ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣèlérí fún Abrahamu, fún Isaaki ati fún Jakọbu, nítorí pé wọn kò fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti o gòke lati Egipti wá, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki yio ri ilẹ na ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu: nitoriti nwọn kò tẹle mi lẹhin patapata.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 32:11
9 Iomraidhean Croise  

Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà.


Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.


“Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.”


“Kò sí ọ̀kan nínú ìran búburú yìí tí yóò dé ilẹ̀ rere tí mo ti búra láti fún àwọn baba ńlá a yín.


Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín: Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí Olúwa ti búra wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan