Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 30:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 “Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Obinrin tí ó bá jẹ́ opó ati obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ wọn. Wọ́n sì gbọdọ̀ yẹra fún ohun gbogbo tí wọn bá ṣe ìlérí láti yẹra fún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ṣugbọn gbogbo ẹjẹ́ opó, ati ti obinrin ti a kọ̀silẹ, ti nwọn fi dè ara wọn, yio wà lọrùn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 30:9
6 Iomraidhean Croise  

“ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.


“Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra,


Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.


Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru.


Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láààyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà.


tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan