Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 30:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 ó níláti ṣe gbogbo ohun tí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́ ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ẹjẹ́ rẹ̀ yio duro, ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 30:7
7 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé: “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ; ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ. Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”


Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”


“Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè,


Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.


Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láààyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà.


Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”


Elkana ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa sá à mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan