Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 30:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, obinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba sọ wọn dasan patapata li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ohunkohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade nipasẹ̀ ẹjẹ́ rẹ̀, tabi nipasẹ̀ ìde ọkàn rẹ̀, ki yio duro: ọkọ rẹ̀ ti sọ wọn dasan; OLUWA yio si darijì i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 30:12
10 Iomraidhean Croise  

Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà naà àwa ní oúnjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi


Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”


Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù, fun gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, a ó sì dáríjì wọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti mú ọrẹ àfinásun wá fún Olúwa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀.


Àlùfáà yóò ṣe ètùtù níwájú Olúwa fún ẹni tó ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, tí wọ́n bá ṣe ètùtù fún un, a ó sì dáríjì í.


tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró.


Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀.


Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un.


Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.


Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kristi ni orí olúkúlùkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kristi sì ní Ọlọ́run.


Elkana ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa sá à mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan