Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Fi ẹ̀yà Lefi jì Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Aaroni nínú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:9
15 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà Dafidi wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé.


Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn: Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: Hemani olùkọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samuẹli,


Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili: Àwọn ọmọ Ṣiha, Hasufa, Tabboati,


Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose.


Wọ́n sì tún mú ogúnlénígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili wá—àwọn ènìyàn tí Dafidi àti àwọn ìjòyè rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.


Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Israẹli ti yà yín sọ́tọ̀ lára ìjọ Israẹli yòókù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ Olúwa àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn?


Kí o sì mú àwọn ènìyàn rẹ ará Lefi láti ẹ̀yà ìran rẹ láti dàpọ̀ mọ́ ìwọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ níwájú Àgọ́ ẹ̀rí.


Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Israẹli nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́.


Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi.


Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli.


Mo sì ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Israẹli


Nínú Israẹli, mo fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Israẹli àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-ààrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.”


Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni.


Nítorí náà a wí pé: “Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga, ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn, ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan