Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”
Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rú ẹbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
Kí o sì mú àwọn ènìyàn rẹ ará Lefi láti ẹ̀yà ìran rẹ láti dàpọ̀ mọ́ ìwọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ níwájú Àgọ́ ẹ̀rí.
Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sinai, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Eleasari àti Itamari ló ṣiṣẹ́ àlùfáà nígbà ayé Aaroni baba wọn.