Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:47 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

47 ìwọ yóò gba ṣékélì márùn-ún (5) lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gera.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

47 Kí o gba ṣekeli marun-un-marun-un lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

47 Ani ki o gbà ṣekeli marun-marun li ori ẹni kọkan, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́ ni ki o gbà wọn; (ogun gera ni ṣekeli kan):

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:47
10 Iomraidhean Croise  

Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa.


Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n àti ẹgbẹ̀rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́.


Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì márùn-dínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ minas kan.


Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́, ogún gera.


kí iye owó ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sí ọgọ́ta ọdún jẹ́ àádọ́ta òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà, gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ṣékélì ti ibi mímọ́ Olúwa;


Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin.


Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn-ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọ̀n ogún (20) gera.


Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli tó lé yìí, ni kí o kó fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀.


Mose sì gba egbèje ṣékélì ó dín márùn-dínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli.


Ọrẹ rẹ̀ jẹ́: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan