Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:45 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

45 Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi. Èmi ni Olúwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

45 “Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli, ati ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn wọn. Àwọn ọmọ Lefi yóo sì jẹ́ tèmi. Èmi ni OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

45 Gbà awọn ọmọ Lefi ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi nipò ohun-ọ̀sin wọn; awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi; Emi li OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:45
7 Iomraidhean Croise  

“Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi,


Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo.


Olúwa tún sọ fún Mose pé,


Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli.


Èmi fúnra mi ti yan àwọn arákùnrin rẹ tí í ṣe ọmọ Lefi kún àwọn ọmọ Israẹli yòókù, wọn jẹ́ ẹ̀bùn fún ọ, èyí ni a fún Olúwa láti ṣe iṣẹ́ tí ó wà ní àgọ́ ìpàdé.


Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi lè tẹ̀síwájú” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan