Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sinai, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Eleasari àti Itamari ló ṣiṣẹ́ àlùfáà nígbà ayé Aaroni baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n fi iná tí a kò yà sí mímọ́ rúbọ sí OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. Wọn kò bímọ. Nítorí náà Eleasari ati Itamari ní ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní ìgbà ayé Aaroni, baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:4
7 Iomraidhean Croise  

Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni: Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.


Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250) tí wọ́n mú tùràrí wá.


Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ.


Mú Aaroni àti ọmọ rẹ̀ Eleasari lọ sí orí òkè Hori.


Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)


Olúwa sọ fún Mose pé,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan