Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:36 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

36 Àwọn ìran Merari ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

36 Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn igi àkànpọ̀ ibi mímọ́, ati àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

36 Iṣẹ itọju awọn ọmọ Merari yio si jẹ́ apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo ìsin rẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:36
14 Iomraidhean Croise  

Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kasia mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin mẹ́rin.


Ìwọ ó sì ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, àti òpó igi ṣittimu márùn-ún tí a sì fi wúrà bò. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ márùn-ún fún wọn.


“àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;


Èèkàn àgọ́ náà fún àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn;


Wọ́n sì ṣe òpó igi ṣittimu mẹ́rin fún un wọ́n sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà. Wọ́n sì ṣe àwọn ìkọ́ wúrà fún wọn, wọ́n sì dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rin mẹ́rin fún wọn.


Wọ́n sì mú tabanaku náà tọ Mose wá: àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;


Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili. Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.


Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.


Ó fún àwọn ọmọ Merari ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan