Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:32 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

32 Eleasari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo máa ṣe alákòóso àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi, òun ni yóo sì máa ṣe àkóso àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

32 Eleasari ọmọ Aaroni alufa ni yio si ṣe olori awọn olori awọn ọmọ Lefi, on ni yio si ma ṣe itọju awọn ti nṣe itọju ibi-mimọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:32
12 Iomraidhean Croise  

Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, Seraiah olórí àwọn àlùfáà, Sefaniah àlùfáà kejì, àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta.


ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olórí àlùfáà—


Ó sì wí fún mi pé, “yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà.


Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.


Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari.


“Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”


Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un.


Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó-lé-ọgbọ̀n (2,630).


Wọ́n le máa ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ nínú àgọ́ ìpàdé ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Báyìí ni kí o ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Lefi.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan