Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 3:15 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 “Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

15 “Ka iye àwọn ọmọkunrin Lefi gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ oṣù kan lọ sókè.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Kaye awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn: gbogbo ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ni ki iwọ ki o kà wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 3:15
17 Iomraidhean Croise  

Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn.


Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi àwọn tí ó sì wá mi rí mi.


“Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé: “Báyìí ni Olúwa wí, “ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ, ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù, nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.


Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,


Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.


A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù.


Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.


Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.


Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.


Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500).


Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rin ó-lé-ẹgbẹ̀ta (8,600), tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́.


Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).


Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó-dínméje (22,273).


Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.


Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan