Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 28:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àárọ̀ ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àṣáálẹ́,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ọdọ-agutan kan ni ki iwọ ki o fi rubọ li owurọ̀, ati ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 28:4
12 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọtẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì ṣí ìdáhùn, kò sì ṣí ẹni tí ó kà á sí.


Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ.


Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Olúwa, tí ó ti fún Israẹli.


Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.


Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mọ́júmọ́.


Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gebrieli ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣálẹ́.


Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.


Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́-àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.


Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́.


Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi.


Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan