Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé.