Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 28:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Olúwa sọ fún Mose pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 OLUWA sọ fún Mose

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 28:1
17 Iomraidhean Croise  

Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.


Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé.


Nígbà náà, Jehoiada tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ẹni tí Dafidi ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ẹbọ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mose, pẹ̀lú ayọ̀ àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti pàṣẹ.


Ọba fi sílẹ̀ láti ara ohun ìní rẹ̀ fun ẹbọ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ẹbọ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn gẹ́gẹ́ bi a ti ṣe kọ ọ́ nínú òfin Olúwa.


nípa ìlànà ojoojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mose wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àìwúkàrà, ní àjọ ọ̀sẹ̀ méje àti àjọ àgọ́.


Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀.


Nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.


Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ, Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.


“ ‘Nínú èyíkéyìí èdè-àìyedè, àwọn àlùfáà ní yóò dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn, wọn sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi ní mímọ́.


Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ-aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àsè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ́ ìsinmi ni gbogbo àjọ̀dún tí a yàn ní ilé Israẹli. Òun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Israẹli.


“ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan.


Aaroni mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́.


Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.


“Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’


Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,


Ẹ̀yin ń kíyèsi ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún.


Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan